Yo awon ti nsegbe
1. Yo awon ti nsegbe, sajo eni nku,
F’ anu ja won kuro ninu ese,
Ke f’ awon ti nsina, gb’ eni subu ro,
So fun won pe, Jesu le gba won la,
Ref
Yo awon ti nsegbe, sajo eni nku,
Alanu ni Jesu, yio gbala.
2. Bi nwon o tile gan, sibe O nduro
Lati gb’ omo t’ o ronupiwada;
Sa f’ itara ro won, sir o won jeje,
On o dariji, bi nwon ba gbagbo.
3. Yo awon ti nsegbe, – ise tire ni;
Oluwa yio f’ agbara fun o:
Fi suru ro won, pada s’ ona toro,
So f’ asako p’ Olugbala ti ku,