Wakati Adura Didun

 


Wakati adura didun! T’o gbe mi lo kuro l’ayé,
Lo ‘waju ite Baba mi, Ki nso gbogbo edun mi fun;
Nigba ‘banuje ati’aro, Adua l’abo fun okan mi:
Emi si bo lowo Esu, ‘Gbati mo ba gb’adua didun


Wakati adura didun! Iye re y’o gbe ebe mi,
Lo sod’ eni t’o se ‘leri, Lati bukun okan adua:
B’O ti ko mi, ki nw‘ oju Re, Ki ngbekele, ki nsi gba gbo:
Nno ko gbogb’ aniyan mi le, Ni akoko adua didun,


Wakati adura didun! Je ki nma r’itunu re gba,
Titi uno fi d’oke Pisga, Ti umo r’ile mi l‘ okere,
Nno bo ago ara sile,  Nno gba ere ainipekun:
Nno korin bi mo ti nfo lo, O digbose! Adua didun.

https://youtu.be/UKvgpaNIFwM

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *