Wa Sodo Jesu

 


1. Wa sodo Jesu, mase duro,
L’oro Re l’O ti f’ona han wa,
O duro Ni Arin wa loni,
O nwi jeje pe, “Wa.”


Refrain
Ipade wa yio je ayo,
Gba okan wa ba bo lowo ese,
T’a o si wa pelu Re, Jesu,
Ni ile wa lailai.


2. “Je k’omode wa,” A! gbohun Re!
Je k’okan gbogbo ho fun ayo;
Ki asi yan Oun l’ayanfe wa;
Ma duro, sugbon wa.


3. Tun ro, O wa pelu wa loni,
F’eti s’ofin Re, k’o si gboran,
Gbo b’ohun Re ti n wi pele pe,
“Eyin omo Mi wa!”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *