Ru Iti Wole
Funrugbin l’ owuro, irugbin inu ‘re
Funrugbin l’ osan gan, ati ni ale
Duro de ikore ati ‘gba ikojo
A o f’ ayo pada, ru iti wole.
Refrain:
Ru iti wole, ru iti wole
A o f’ ayo pada ru iti wole
Ru iti wole, ru iti wole
A o f’ ayo pada, ru iti wole.
Funrugbin nin’ orun, ati nin’ojiji
Laiberu ikuku, tabi otutu
Nigbati ikore, ati lalaa ba pin
A o f’ ayo pada, ru iti wole.
Bi a tile nf’ omije sise f’ Oluwa
Adanu ta nri le m’ okan wa gbogbe
Gbat’ ekun ba dopin, yio ki wa ku abo
A o f’ ayo pada, ru iti wole