Oluwa li Apata wa

 


Oluwa li apata wa
Lodo Re l’awa o sa si
Ohun kohun t’o wu ko de
Abo ninu iji ‘ponju.


Egbe:
Jesu li Apata f’awon alare
Fun alare, fun alare
Jesu li Apata f’awon alare
Abo ninu iji ‘ponju.(Amin)


Abo l’oje fun wa l’osan
Olugbeja wa ni l’oru
Ota o le deru ba wa
Abo ninu iji iponju.


Iji nla le ja yi wa ka
Ikun omi le n’de si wa
A ti r’ibit’a o sa si
Abo ninu iji ‘ponju.


Apata Aiyeraiye wa
Ilu abo wa t’o sowon
Sunmo wa lati se ‘ranwo
Abo ninu iji ‘ponju.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *