Ninu Kristi nikan
N’nu Krist’ nikan nireti mi,
O’n n’imọlẹ, agbar’, orin mi;
Igun-ile yii, Apata yii,
Wa sibẹ nin’ ọda ‘ti’ji.
Ifẹ giga, ibalẹ okan,
‘Gbati ‘bẹru, idamu pin!
Olutunu, Oun ni mo ni,
Ninu ‘fẹ Kristi mo duro.
N’nu Krist’ nikan, t’O wa leeyan
Ọlọrun to wa bí ìkókó!
Ẹbun ‘fẹ yii at’ ododo
T’awọn t’O wa gbala kẹgan:
Lori igi ti Jesu ku,
Irunu Ọlọrun walẹ-
Tori pẹ’ṣẹ wa lo gberu;
Ninu ‘ku Kristi ni mo ye.
Nibẹ ‘nu ‘lẹ l’oku Rẹ wa
Imọlẹ aye t’ookun pa:
Lẹyin eyi lọjọ ologo
O ji dide kuro ‘nu oku!
B’O si ti duro n’iṣẹgun
Mo bọ lọwọ egun ẹṣẹ,
Mo jẹ Tirẹ, Oun temi-
Emi ta fẹjẹ Kristi ra.
Niye, niku, ko si ‘foya,
Agbara Kristi ‘nu mi ni;
Lati ‘bẹrẹ titi dopin,
Jesu gba ayanmo mi mu.
Ogun eṣu, ete aye
Ki yoo le gba mi lowo Rẹ,
‘Ti y’ O fi de, tabi pe mi
N o duro ‘nu agbara Kristi.