Nigbati igbi aye yi
Nigbati ‘gbi aye yi ba nyi lu o, To si dabi enipe gbogbo re pin,
Ka ibukun re, Siro won l’okokan, Ise oluwa yo je ‘yanu fun o.
Refrain
Ka ‘bukun re, ka won l’okokan, Ka ‘bukun re, wo ‘se Olorun ;
Ka ‘bukun re, ka won l’okokan, Ka ‘bukun re, wa ri ‘se t’Olorun se.
Eru aniyan ha nwo ‘kan re l’orun! Ise t’a pe o si ha soro fun O;
Ka ‘bukun re, ‘yemeji yo si fo lo, Orin iyin ni yo si gb’enu re kan.
‘Gbat’ o ba nwo awon oloro aye, Ronu oro ti Jesu ti se leri;
Ka ibukun re, owo ko le ra won, Ere re l’orun ati ‘le re l’oke.
Ninu gbogbo ayidayida aye, Mase foya, Olorun tobi julo;
Ka ‘bukun re, awon angel‘ yo to o, Won yo si ran o lowo titi d’opin Amin.
https://youtu.be/fQoL9VYLPBA