Mo J’alejo Nihin

 


Mo j’alejo nihin, ‘nu ile ajeji,
Ile mi jin rere, lor’ebute wura;
Lati je iranse n’koja okun lohun
Mo n sise nihin f’Oba mi.


Refrain:
Eyi nise ti mo wa je,
‘Se tawon angel’ nko lorin
E b’Olorun laja l’Oluwa Oba wi
E ba Olorun yin laja.


Eyi lase Oba, keniyan n’bi gbogbo
Ronupiwada kuro ninu ‘dekun ese,
Awon to ba gboran yio joba pelu Re,
Eyi nise mi f’Oba mi.


Ile mi dara ju petele Sharon lo,
Nibiti ‘ye ainipekun atayo wa;
Ki n so fun araye, bi won se lee gbebe
Eyi nise mi f’Oba mi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *