Mimo, Mimo, Mimo, Olodumare

 


1. Mimo, mimo,mimo, Olodumare
Ni kutukutu n’iwo O gbo orin wa
Mimo, mimo, mimo ! Oniyonu julo
Ologo meta, lae Olubukun


2. Mimo, mimo, mimo ! awon t’orun nyin
Won nfi ade wura won le ‘le yi ‘te ka
Kerubim, serafim nwole niwaju Re
Wo t’o ti wa, t’O si wa titi lae.


3. Mimo, mimo,mimo ! b’okunkun pa o mo
Bi oju elese ko le ri ogo re
Iwo nikan l’O mo, ko tun s’elomiran
Pipe ‘nu agbara ati n’ife.


4. Mimo, mimo, mimo ! Olodumare
Gbogbo ise Re n’ile l’oke l’o nyin O
Mimo, mimo, mimo ! Oniyonu julo
Ologo meta lae Olubunkun ! Amin.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *