Ma Koja Mi Olugbala

 


1. Ma koja mi, Olugbala, Gbo adura mi,
‘Gba t’Iwo ba n p’elomiran, Mase koja mi!


CHORUS
Jesu! Jesu! Gbo adura mi!
Gba t’Iwo ba n p’elomiran,
Mase koja mi.


2. N’ite anu je k’emi ri, Itura didun;
Teduntedun ni mo wole, Jo ran mi lowo.


3. N’igbekele itoye Re, L’em’ o w’oju Re;
Wo ‘banuje okan mi san, F’ife Re gba mi.


4. ‘Wo orisun itunu mi, Ju ‘ye fun mi lo;
Tani mo ni l’ayé l’orun Bikose Iwo?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *