Ma f’ara fun ‘danwo, nitor’

 


1. Ma f’ara fun ‘danwo, nitor’ ese ni,
Isegun kan yo tun fun O l’agbara;
Ja bi okunrin, si bori ‘fekufe,
Sa tejumo Jesu, y’O mu o laja.


Ref
Bere ‘ranwo at’agbara lodo Olugbala,
O se tan fun iranwo, Oun y’O mu o la ja (Amin.)


2. Ma kegbe buburu, ma soro ibi,
Mase pe oruko Olorun l’asan;
Je eni ti nronu at’olotito;
Sa tejumo Jesu, y’O mu o la ja.


3. Olorun y’O f’ade f’eni t’o segun,
Ao fi ‘gbagbo segun, b’ota nde si wa;
Kristi y’O so agbara wa di otun,
Sa tejumo Jesu, y’O mu o la ja.

https://youtu.be/rhwsc_SjA9o

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *