Loroke leyin ilu
1. Lor’oke lehin ‘lu, l’agbelebu kan wa
Apẹrẹ iya at’ egan
Ọkan mi fa sibe, s’Olufẹ mi ọwọn
T’a pa f’ẹsẹ gbogbo aiye.
Refrain:
Un o gbe agbelebu Rẹ naa ru
Titi un o fi de ibi ere
Emi o rọmọ agbelebu naa,
K’emi le de ade nikẹhin
2. Lor’ agbelebu yi, ti araiye kẹgàn
On l’o si lẹwa loju mi,
Nitori’ Ọm’Ọlọrun, bọ ogo Rẹ silẹ
O si ti ru u lo si Kalfari
3. L’ar’ agbelebu yi, l’eje mimo san si,
O lewa pupo loju mi
Toripe lori re, Jesu jiya fun mi
O f’ese ji, o we mi mo
4. Emi y’o j’olootọ, S’enit’o ku fun mi,
Un o yo s’ẹgan at’ ‘tiju
Nigbooṣe y’o pe mi lọ ‘le aiyeraiye,
Ki nle pin ninu ogo Rẹ