Ki N Mo Nipa Jesu Sii
Mo fe mo nipa Jesu sii,
F’or’ ofe Re h’ elomiran;
Ki n le ri ‘gbala kikun Re,
Ki n mo ‘fe ‘ni to ku fun mi.
Egbe:
Ki n mo nipa Jesu sii,
Ki n mo nipa Jesu sii;
Ki n le ri ‘gbala kikun Re,
Ki n mo ‘fe ‘ni to ku fun mi
N o ko nipa Jesu sii,
Ki n da ‘fe Re mimo mo si i;
K’ Em’ Olorun j’oluko mi,
Fi ona ti Kristi han mi.
Ki n mo Jesu si n’oro Re,
Ki n ma b’Oluwa mi soro;
Ki n si gbo ‘ro Re lokokan,
So ‘ro ‘tito Re di t’emi.
Ki n mo Jesu l ‘ori ‘te Re,
Pel’ oro gbogbo Ogo Re;
Mo bi’joba Re ti n po si,
Bibo Re Oba ‘lafia