Jesu san gbogbo
1. KO s’ ohun t’ o ku kin se,
B’ o ti wu k’ o kere;
Jesu ku, O san gbogbo
Igbese ti mo je.
Refrain
Jesu san gbogbo,
‘Gbese ti mo je;
Jesu ku, O san gbogbo
Igbese ti mo je.
2. Gbat’ O ti ite Re w’ aiye,
T’ O jiya, t’ O si ku,
A ti s’ ohun gbogbo tan:
“O pari” ni igbe Re.
3. En’ are t’ o ti nsise,
Eredi lala re?
Dekun ‘se se, t’ase tan,
Li ona ti o ti jin.
4. Afi b’ of’ igbagbo ro
Mo ‘se Jesu nikan,
Ise ko n’ iye ninu,
O kangun sinu iku.
5. Da oku ‘se re sile,
Da won s’ s’ ese Jesu;
Duro ninu Re nikan
Ni pipe ati ogo.