Isun Kan Wa to kun f’eje

 


Isun kan wa to kun f’eje,
T‘o ti ’ha Jesu yo.
Elese mokun ninu re,
O bo ninu ebi.


‘Gbamo figbagbo r’isun na,
Ti nsan fun eje Re,
Irapada d’orin fun mi
Ti uno ma ko titi.


Orin t’odun ju eyi lo,
Li emi o ma ko:
‘Gba t’akololo ahon yii
Ba dake niboji.


Mo gbagbo p’O pese fun mi
Bi mo tile s’aiye
Ebun ofe t’a feje ra,
Ati duru wura.


Duru t’a tow‘ Olorun se,
Ti ko ni baje lae:
Ti ao ma fi yin Baba wa,
Oruko Re nikan. Amin