Ija d’opin ogun si tan
Ija dopin oguun si tan
Olugbala jagun molu
Orin ayo la o ma ko
ALLELUIA!!
Gbogbo ipa n’iku ti lo
Sugbon Jesu f’ogun re ka
Aiye e ho iho ayo
Alleluia!
Ojo meta na ti koja
O jinde kuro ninu oku
E f’ogo fun Oluwa wa
ALLELUIA!
O d’ewon orun apadi
O silekun orun sile
E korin yin segun re
ALLELUIA!
Jesu, nipa iya t’oje
Gba wa lowo oro iku
K’a le ye, ka si ma yin o
ALLELUIA! AMIN.