Idapo didun ti nfunni l’ayo
1. Idapo didun ti nfunni l’ayo
Mo ngbekele Jesu Oluwa
Ifaiyabale at’itelorun
F’awon to ngbekele Oluwa
Egbe
Mo ngbekele
Ko s’ewu biti Jesu wa
Mo ngbekele
Mo ngbekele Jesu Oluwa
2. A! b’o ti dun to lati ma rin lo
Mo ngbekele Jesu Oluwa
Ona na nye mi si lojojumo
Mo ngbekele Jesu Oluwa
3. Ko si ‘beru mo ko si ‘foiya mo
Mo ngbekele Jesu Oluwa
Okan mi bale pe mo ni Jesu
Mo ngbekele Jesu Oluwa.