Gbo eda orun nkorin

 


1. Gbo eda orun nkorin,
“Ogo fun Oba t’ a bi.”
“Alafia l’ aiye yi,”
Olorun ba wa laja,
Gbogbo eda, nde l’ ayo,
Dapo mo hiho t’ orun;
W’ Alade Alafia!
Wo Orun ododo de.


Ref
Gbo eda orun nkorin
Gbo fun Oba t’ a bi.


2. O bo ‘go Re s’ apakan,
A bi, k’ enia ma ku,
A bi, k’ O gb’ enia ro,
A bi, k’ O le tun wa bi.
Wa Ireti enia,
Se ile Re ninu wa;
Nde, Iru Omobirin
Bori Esu ninu wa;


3. Pa aworan Adam run,
F’ aworan Re s’ ipo re;
Jo, masai f’ Emi Re kun
Okan gbogb’ onigbagbo.
Ogo fun Oba t’ a bi
Je ki gbogbo wa gberin.
“Alafia l’ aiye yi,
Olorun ba wa laja.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *