Fa mi mora

 


Tire lemi se, mo ti gbohun Re
O nso ife Re si mi.
Sugbon mo fe n’de lapa igbagbo,
Ki nle tubo sunmo O


Refrain:
Fa mi mora, mora, Oluwa
Sib’agbelebu t’O ku
Fa mi mora, mora, mora Oluwa
Sib’eje Re to niye


Ya mi si mimo fun ise Tire,
Nipa ore-ofe Re:
Je ki n fi okan igbagbo woke,
Kife mi te siTire.


A! Ayo mimo ti wakati kan
Ti mo lo nib’ite Re;
‘Gba mo gbadura si Olorun mi,
Mo ba soro bi ore,


Ijinle ife nbe ti ko le mo
Titi n o koja odo
Ayo giga ti emi ko le so
Titi n o fi wa simi,

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *