Jesu Ni Gbogbo Aye Fun Mi

 


Verse 1
JESU ni gbogb’ aiye fun mi,
Iye at’ ayo mi,
Agbara mi lojojumo,
L’ aisi Re mo subu;
Ni ‘banuje On ni mo to,
Nitori ko s’ eni bi Re,
Ni ‘banuje O m’ ayo wa,
Ore mi.


Verse 2
Jesu ni gbogb’ aiye fun mi,
Ore n’ igba ‘danwo,
Fun ibukun On ni mo to,
Mo ni lopolopo.
O m’ orun ran, at’ ojo ro,
Ikore wura si npo si,
Imole, imole, etc
Orun ojo at’ ikore.
Ore mi.


Verse 3
Jesu ni gbogb’ aiye fun mi,
Nko si ni tan On je,
O ti buru to bi mo se;
Gbat’ On ko tan mi je?
Nitito Re nko le sina,
On toju mi losan loru,
Ni tito Re losan loru,
Ore mi.


Verse 4
Jesu ni gbogb’ aiye fun mi,
Nko fe elomiran,
Ngo gbekele nisisiyi,
T’ ojo aiye nkoja;
Aiye ewa lodo re na,
Aiye ewa ti ko l’ opin,
Iye, ayo ainipekun,
Ore mi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *