Ayo B’aiye! Oluwa De
Ayo b’aiye! Oluwa de;
K’aiye gba Oba re;
Ki gbogbo okan mura de,
K’aiye korin soke K’aiye korin soke
K’aiye, K’aiye korin soke.
Ayo b’aiye! Jesu joba,
E je ‘ka ho f’ayo;
Gbogbo igbe, omi, oke,
Nwon ngberin ayo na, Nwon ngberin ayo na,
Nwon ngberin, Nwon ngberin ayo na.
K’ese on ‘yonu pin laiye,
K’egun ye hun n’ile;
O de lati mu ‘bukun san,
De’bi t’egun gbe de, De’bi t’egun gbe de
De’bi t’egun, De’bi t’egun gbe de.
O f’ oto at‘ ife joba,
O jek’ Oril’ ede
Mo, ododo Ljoba Re,
At’ife ‘iyanu Re, At’ife ‘iyanu Re,
At’ife , at’ife ‘iyanu Re.