A o pa de leti odo

 


A o pa de leti odo,
T’ese angeli ti te;
T’o mo gara bi kristali;
Leba ite olorun?


Egbe
A o pade leti odo
Odo didan, odo didan na
Pel’ awon mimo leba odo
T’o nsan leba ite ni.


Leti bebe odo na yi
Pel’ Olusaguntan wa,
A o ma rin a o ma sin
B’a ti ntele ’pase Re.


K’a to de odo didan naa,
A o s’eru wa kale
Jesu y’o gba eru ese
Awon ti y’o de l’ade.


Nje l’eba odo tutu na,
A o r’oju Olugbala;
Emi wa ki o pinya mo
Yi o korin ogo Re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *