Ọkan mi yin Ọba ọrun

 

Ọkan mi yin Ọba ọrun Mu ọrẹ wa sọdọ Rẹ;
‘Wọ ta wosan, t’ a dariji, Tal’ aba ha yin bi Rẹ?
Yin Oluwa, Yin Oluwa, Yin Ọba ainipẹkun.


Yin, fun anu t’ o ti fi han, F’ awọn Baba ‘nu pọnju;
Yin I Ọkan na ni titi, O lọra lati binu,
Yin Oluwa, Yin Oluwa, Ologo n’ nu otitọ.


Bi baba ni O ntọju wa, O si mọ ailera wa;
Jẹjẹ l’ o ngbe wa lapa Rẹ, Ogba wa lọwọ ọta,
Yin Oluwa, Yin Oluwa, Anu Rẹ, yi aye ka.


Angel’, ẹ jumọ ba wa bọ, Eyin nri lojukoju,
Orun, Oṣupa, ẹ wol Ati gbogbo agbaye,
E ba wa yin,E ba wa yin, Ọlọrun Olotitọ.

or


Ọkan mi yin Ọba ọrùn
Mu ọrẹ wa s’ọdọ Rẹ
‘Wọ t’a wosan t’a dariji
Ta laba ha yin bi Rẹ
Yin Oluwa yin Oluwa
Yin Ọba àìnípẹkun.


Yin fún anu t’O ti fihan
F’awọn Baba ‘nu pọnju
Yin l’ọkan na ni titi
Ọlọra lati binu
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Ologo n’nu òtítọ.


Bi baba ni O ntọjú wa,
O si mọ ailera wa
Jẹjẹ l’o ngbe wa l’apa Rẹ,
O gba wa lọwọ ọta,
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Anu Rẹ yi aiye ka.


A ngba b’itana eweko
T’afẹfẹ nfẹ t’ o si nrọ
‘Gbati a nwa, ti a sì nku,
Ọlọrun wa bakanna,
Yin Oluwa, yin Oluwa
Ọba alainipẹkun.


Angẹl, ẹ jumọ ba wa bọ,
Ẹnyin nri lojukoju
Orun osupa ẹ wolẹ,
Ati gbogbo agbaiye
Ẹba wa yin, Ẹba wa yin
Ọlọrun Olotitọ. Amin

https://youtu.be/QpElh7lEhzE

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *